1 Samuẹli 6:16
1 Samuel 6:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn aláṣẹ Filistini márààrún rí gbogbo èyí, wọ́n sì padà ní ọjọ́ náà sí Ekroni.
1 Samuel 6:16 in English
1 Samuel 6:16 · Berean Standard Bible
And when the five rulers of the Philistines saw this, they returned to Ekron that same day.
Context
14Kẹ̀kẹ́ ẹrù wá sí pápá Joṣua ti Beti-Ṣemeṣi, níbẹ̀ ni ó ti dúró ní ẹ̀bá àpáta ńlá kan. Àwọn ènìyàn gé igi ara kẹ̀kẹ́ ẹrù sí wẹ́wẹ́ wọ́n sì fi àwọn màlúù náà rú ẹbọ sísun sí Olúwa. 15Àwọn ará Lefi gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa wá sí ìsàlẹ̀ pẹ̀lú àpótí tí ohun èlò wúrà wà níbẹ̀, wọ́n sì gbé wọn ka orí àpáta ńlá náà. Ní ọjọ́ náà, àwọn ará Beti-Ṣemeṣi rú ẹbọ sísun, wọ́n sì ṣe ìrúbọ sí Olúwa. 16Àwọn aláṣẹ Filistini márààrún rí gbogbo èyí, wọ́n sì padà ní ọjọ́ náà sí Ekroni. 17Èyí ni kókó wúrà tí àwọn Filistini fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀bi ọ̀kọ̀ọ̀kan fún Aṣdodu, ọ̀kan ti Gasa, ọ̀kan ti Aṣkeloni, ọ̀kan ti Gati, ọ̀kan ti Ekroni. 18Wúrà eku ẹ̀lírí jẹ́ iye ìlú tí àwọn aláṣẹ Filistini márààrún ti wá, ìlú olódi pẹ̀lú ìletò wọn. Àpáta ńlá náà, lórí èyí tí a gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa lé jẹ́ ẹ̀rí títí di òní ní oko Joṣua ará Beti-Ṣemeṣi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.