1 Samuẹli 5:10
1 Samuel 5:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run lọ sí Ekroni. Bí àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ṣe wọ Ekroni, àwọn ará Ekroni fi igbe ta pé, “Wọ́n ti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Israẹli tọ̀ wá wá láti pa wá àti àwọn ènìyàn wa.”
1 Samuel 5:10 in English
1 Samuel 5:10 · Berean Standard Bible
So they sent the ark of God to Ekron, but as it arrived, the Ekronites cried out, “They have brought us the ark of the God of Israel in order to kill us and our people!”
Context
8Nígbà náà ni wọ́n pè gbogbo àwọn olórí Filistini jọ wọ́n sì bi wọ́n pé, “Kí ni a ó ṣe pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àwọn Israẹli?”
Wọ́n dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí á gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àwọn Israẹli lọ sí Gati.” Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Israẹli. 9Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti gbé e, ọwọ́ Olúwa sì wá sí ìlú náà, ó mú jìnnìjìnnì bá wọn. Ó sì pọ́n àwọn ènìyàn ìlú náà lójú, ọmọdé àti àgbà, pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn oníkókó. 10Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run lọ sí Ekroni.
Bí àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ṣe wọ Ekroni, àwọn ará Ekroni fi igbe ta pé, “Wọ́n ti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Israẹli tọ̀ wá wá láti pa wá àti àwọn ènìyàn wa.” 11Nígbà náà ni wọ́n pe gbogbo àwọn olórí àwọn Filistini jọ wọ́n sì wí pé, “Ẹ gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àwọn Israẹli lọ: ẹ jẹ́ kí ó padà sí ààyè rẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò pa wá àti àwọn ènìyàn wa.” Ikú ti mú jìnnìjìnnì bá àwọn ará ìlú, ọwọ́ Ọlọ́run sì wúwo lára wọn. 12Àwọn tí kò kú wọ́n pọ́n wọn lójú pẹ̀lú ààrùn oníkókó, ẹkún ìlú náà sì gòkè lọ sí ọ̀run.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.