1 Samuẹli 4:17
1 Samuel 4:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọkùnrin tí ó mú ìròyìn náà wá dáhùn pé, “Israẹli sá níwájú àwọn Filistini, ìṣubú àwọn ọmọ-ogun náà sì pọ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ méjèèjì, Hofini àti Finehasi, wọ́n kú, wọ́n sì ti gba àpótí ẹ̀rí Olúwa lọ.”
1 Samuel 4:17 in English
1 Samuel 4:17 · Berean Standard Bible
The messenger answered, “Israel has fled before the Philistines, and there has been a great slaughter among the people. Your two sons, Hophni and Phinehas, are both dead, and the ark of God has been captured.”
Context
15Eli sì di ẹni méjìdínlọ́gọ́run (98) ọdún, tí ojú rẹ̀ di bàìbàì, kò sì ríran mọ́. 16Ọkùnrin náà sọ fún Eli, “Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti ibi ogun náà ni: mo sá láti ibi ogun náà wá lónìí.”
Eli sì béèrè pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀ ọmọ mi?” 17Ọkùnrin tí ó mú ìròyìn náà wá dáhùn pé, “Israẹli sá níwájú àwọn Filistini, ìṣubú àwọn ọmọ-ogun náà sì pọ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ méjèèjì, Hofini àti Finehasi, wọ́n kú, wọ́n sì ti gba àpótí ẹ̀rí Olúwa lọ.” 18Nígbà tí ó dárúkọ àpótí ẹ̀rí Olúwa, Eli sì ṣubú sẹ́yìn kúrò lórí àga ní ẹ̀gbẹ́ bodè, ọrùn rẹ̀ ṣẹ́, ó sì kú, nítorí tí ó jẹ́ arúgbó ọkùnrin, ó sì tóbi, ó ti darí àwọn Israẹli fún ogójì ọdún. 19Aya ọmọ rẹ̀, ìyàwó Finehasi, ó lóyún ó súnmọ́ àkókò àti bí. Nígbà tí ó gbọ́ ìròyìn náà wí pé wọ́n ti gba àpótí ẹ̀rí Olúwa lọ àti wí pé baba ọkọ rẹ̀ àti ọkọ rẹ̀ ti kú, ó rọbí ó sì bímọ, ó sì borí ìrora ìrọbí náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.