1 Samuẹli 4:13
1 Samuel 4:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ó sì dé, Eli sì jókòó sórí àga rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà, ó ń wò, ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ nítorí àpótí ẹ̀rí Olúwa. Nígbà tí ọkùnrin náà wọ ìlú tí ó sì sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, gbogbo ìlú bẹ̀rẹ̀ sí sọkún.
1 Samuel 4:13 in English
1 Samuel 4:13 · Berean Standard Bible
When he arrived, there was Eli, sitting on his chair beside the road and watching, because his heart trembled for the ark of God. When the man entered the city to give a report, the whole city cried out.
Context
11Wọ́n gba àpótí ẹ̀rí Olúwa, àwọn ọmọkùnrin Eli méjèèjì sì kú, Hofini àti Finehasi. 12Lọ́jọ́ kan náà tí ará Benjamini kan sá wá láti ojú ogun tí ó sì lọ sí Ṣilo, aṣọ rẹ̀ sì fàya pẹ̀lú eruku lórí rẹ̀. 13Nígbà tí ó sì dé, Eli sì jókòó sórí àga rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà, ó ń wò, ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ nítorí àpótí ẹ̀rí Olúwa. Nígbà tí ọkùnrin náà wọ ìlú tí ó sì sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, gbogbo ìlú bẹ̀rẹ̀ sí sọkún. 14Eli gbọ́ ìró ohùn ẹkún náà ó sì béèrè pé, “Kí ni ìtumọ̀ ariwo yìí?”
Ọkùnrin náà sì sáré tọ Eli wá 15Eli sì di ẹni méjìdínlọ́gọ́run (98) ọdún, tí ojú rẹ̀ di bàìbàì, kò sì ríran mọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.