Native Bible

1 Samuel 26:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ǹjẹ́ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ mi ó sàn sílẹ̀ níwájú Olúwa; nítorí ọba Israẹli jáde láti wá ẹ̀mí mi bi ẹni ń dọdẹ àparò lórí òkè ńlá.”

1 Samuel 26:20 in English

1 Samuel 26:20 · Berean Standard Bible

So do not let my blood fall to the ground far from the presence of the LORD. For the king of Israel has come out to look for a flea, like one who hunts a partridge in the mountains.”

Context

18Òun sì wí pé, “Nítorí kín ni olúwa mi ṣe ń lépa ìránṣẹ́ rẹ̀? Kín ni èmi ṣe? Tàbí ìwà búburú wo ni ó wà lọ́wọ́ mi. 19Ǹjẹ́ èmi bẹ̀ ọ́, ọba, olúwa mi, gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ. Bí ó bá ṣe Olúwa bá ti rú ọ sókè sí mi, jẹ́ kí òun o gba ẹbọ; ṣùgbọ́n bí o bá sì ṣe pé ọmọ ènìyàn ni, ìfibú ni kí wọn ó jásí níwájú Olúwa; nítorí tí wọn lé mi jáde lónìí kí èmi má ba à ní ìpín nínú ilẹ̀ ìní Olúwa, wí pé, ‘Lọ sin àwọn ọlọ́run mìíràn.’ 20Ǹjẹ́ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ mi ó sàn sílẹ̀ níwájú Olúwa; nítorí ọba Israẹli jáde láti wá ẹ̀mí mi bi ẹni ń dọdẹ àparò lórí òkè ńlá.” 21Saulu sì wí pé, “Èmi ti dẹ́ṣẹ̀: yípadà, Dafidi ọmọ mi: nítorí pé èmi kì yóò wa ibi rẹ mọ́, nítorí tí ẹ̀mí mi sì ti ṣe iyebíye lójú rẹ lónìí: wò ó, èmi ti ń hùwà òmùgọ̀, mo sì ti ṣìnà jọjọ.” 22Dafidi sì dáhùn, ó sì wí pé, “Wò ó, ọ̀kọ̀ ọba! Kí ó sì jẹ́ kí ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin rékọjá wá gbà á.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.