Native Bible

1 Samuel 25:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Dafidi sì gbọ́ ní aginjù pé Nabali ń rẹ́ irun àgùntàn rẹ̀.

1 Samuel 25:4 in English

1 Samuel 25:4 · Berean Standard Bible

While David was in the wilderness, he heard that Nabal was shearing sheep.

Context

2Ọkùnrin kan sì ń bẹ ní Maoni, ẹni tí iṣẹ́ rẹ̀ ń bẹ ní Karmeli; ọkùnrin náà sì ní ọrọ̀ púpọ̀, ó sì ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) àgùntàn, àti ẹgbẹ̀rún (1,000) ewúrẹ́: ó sì ń rẹ irun àgùntàn rẹ̀ ní Karmeli. 3Orúkọ ọkùnrin náà sì ń jẹ́ Nabali, orúkọ aya rẹ̀ ń jẹ́ Abigaili; òun sì jẹ́ olóye obìnrin, àti arẹwà ènìyàn; ṣùgbọ́n òǹrorò àti oníwà búburú ni ọkùnrin; ẹni ìdílé Kalebu ni òun jẹ́. 4Dafidi sì gbọ́ ní aginjù pé Nabali ń rẹ́ irun àgùntàn rẹ̀. 5Dafidi sì rán ọmọkùnrin mẹ́wàá, Dafidi sì sọ fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà pé, “Ẹ gòkè lọ sí Karmeli, kí ẹ sì tọ Nabali lọ, kí ẹ sì kí i ni orúkọ mi. 6Báyìí ni ẹ ó sì wí fún ẹni tí ó wà ni ìrora pé, ‘Àlàáfíà fún ọ! Àlàáfíà fún ohun gbogbo tí ìwọ ní!

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.