1 Samuẹli 25:34
1 Samuel 25:34 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítòótọ́, bí Olúwa Ọlọ́run Israẹli tí ń bẹ, tí ó da mi dúró láti pa ọ́ lára bí kò ṣe pé bí ìwọ ti yára tí ó sì wá pàdé mi, nítòótọ́ kì bá tí kù fún Nabali di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀.”
1 Samuel 25:34 in English
1 Samuel 25:34 · Berean Standard Bible
Otherwise, as surely as the LORD, the God of Israel, lives, who has restrained me from harming you, if you had not come quickly to meet me, then surely no male belonging to Nabal would have been left alive by morning light.”
Context
32Dafidi sì wí fún Abigaili pé, “Alábùkún fún ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli, tí ó rán ọ lónìí yìí láti pàdé mi. 33Ìbùkún ni fún ọgbọ́n rẹ, alábùkún sì ni ìwọ, tí ó da mi dúró lónìí yìí láti wá ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, àti láti fi ọwọ́ mi gba ẹ̀san fún ara mi. 34Nítòótọ́, bí Olúwa Ọlọ́run Israẹli tí ń bẹ, tí ó da mi dúró láti pa ọ́ lára bí kò ṣe pé bí ìwọ ti yára tí ó sì wá pàdé mi, nítòótọ́ kì bá tí kù fún Nabali di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀.” 35Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì gba nǹkan tí ó mú wá fún un lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Gòkè lọ ni àlàáfíà sí ilé rẹ, wò ó, èmi ti gbọ́ ohùn rẹ, inú mi sì dùn sí ọ.” 36Abigaili sì tọ Nabali wá, sì wò ó, òun sì ṣe àsè ni ilé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àsè ọba: inú Nabali sì dùn nítorí pé, ó ti mú ọtí ni àmupara; òun kò si sọ nǹkan fún un, díẹ̀ tàbí púpọ̀: títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.