Native Bible

1 Samuel 25:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí ọkùnrin kan bá sì dìde láti máa lépa rẹ, àti máa wá ẹ̀mí rẹ, a ó sì di ẹ̀mí olúwa mi nínú ìdì ìyè lọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run rẹ; àti ẹ̀mí àwọn ọ̀tá rẹ ni a ó sì gbọ̀n sọnù gẹ́gẹ́ bí kànnàkànnà jáde.

1 Samuel 25:29 in English

1 Samuel 25:29 · Berean Standard Bible

And should someone pursue you and seek your life, then the life of my lord will be bound securely by the LORD your God in the bundle of the living. But He shall fling away the lives of your enemies like stones from a sling.*

Context

27Ǹjẹ́ èyí ni ẹ̀bùn tí ìránṣẹ́bìnrin rẹ mú wá fún olúwa mi, jẹ́ kí a sì fi fún àwọn ọmọkùnrin ti ń tọ olúwa mi lẹ́yìn. 28“Èmi bẹ̀ ọ́, fi ìrékọjá arábìnrin rẹ jìn ín, nítorí Olúwa yóò sá ṣe ilé òdodo fún olúwa mi, nítorí pé ó ja ogun Olúwa. Nítorí náà kí a má ri ibi kan ni ọwọ́ rẹ níwọ̀n ìgbà tí ó wà láààyè. 29Bí ọkùnrin kan bá sì dìde láti máa lépa rẹ, àti máa wá ẹ̀mí rẹ, a ó sì di ẹ̀mí olúwa mi nínú ìdì ìyè lọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run rẹ; àti ẹ̀mí àwọn ọ̀tá rẹ ni a ó sì gbọ̀n sọnù gẹ́gẹ́ bí kànnàkànnà jáde. 30Yóò sì ṣe, Olúwa yóò ṣe sí olúwa mi gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìre tí ó ti wí nípa tirẹ̀, yóò sì yàn ọ́ ni aláṣẹ lórí Israẹli. 31Èyí kì yóò sì jásí ìbànújẹ́ fún ọ, tàbí ìbànújẹ́ ọkàn fún olúwa mi, nítorí pé ìwọ ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, tàbí pé olúwa mi gba ẹ̀san fún ara rẹ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí Olúwa ba ṣe oore fún olúwa mi, ǹjẹ́ rántí ìránṣẹ́bìnrin rẹ!”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.