Native Bible

1 Samuel 25:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wí pé, “Olúwa mi, fi ẹ̀ṣẹ̀ yìí yá mi: kí ó sì jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ, èmi bẹ̀ ọ́, sọ̀rọ̀ létí rẹ, kí ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́bìnrin rẹ.

1 Samuel 25:24 in English

1 Samuel 25:24 · Berean Standard Bible

She fell at his feet and said, “My lord, may the blame be on me alone, but please let your servant speak to you; hear the words of your servant.

Context

22Bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, ni ki Ọlọ́run ó ṣe sí àwọn ọ̀tá Dafidi, bi èmi bá fi ọkùnrin kan sílẹ̀ nínú gbogbo èyí tí i ṣe tirẹ̀ títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀.” 23Abigaili sì rí Dafidi, ó sì yára, ó sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì dojúbolẹ̀ níwájú Dafidi, ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀. 24Ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wí pé, “Olúwa mi, fi ẹ̀ṣẹ̀ yìí yá mi: kí ó sì jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ, èmi bẹ̀ ọ́, sọ̀rọ̀ létí rẹ, kí ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́bìnrin rẹ. 25Olúwa mi, èmi bẹ̀ ọ́ má ka ọkùnrin Beliali yìí sí, àní Nabali. Nítorí pé bí orúkọ rẹ̀ ti jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni òun náà rí. Nabali ni orúkọ rẹ̀, àìmoye si wà pẹ̀lú rẹ̀; ṣùgbọ́n èmi ìránṣẹ́bìnrin rẹ kò ri àwọn ọmọkùnrin olúwa mi, ti ìwọ rán. 26Ǹjẹ́ olúwa mi, bi Olúwa ti wà láààyè, àti bí ẹ̀mí rẹ̀ si ti wà láààyè, bi Olúwa sì ti dá ọ dúró láti wá ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, àti láti fi ọwọ́ ara rẹ gba ẹ̀san; ǹjẹ́, kí àwọn ọ̀tá rẹ, àti àwọn ẹni tí ń gbèrò ibi sí olúwa mi rí bi i Nabali.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.