1 Samuẹli 25:1
1 Samuel 25:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Samuẹli sì kú; gbogbo ènìyàn Israẹli sì kó ara wọn jọ, wọ́n sì sọkún rẹ̀ wọ́n sì sin ín nínú ilé rẹ̀ ní Rama. Dafidi sì dìde, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ijù Parani.
1 Samuel 25:1 in English
1 Samuel 25:1 · Berean Standard Bible
When Samuel died, all Israel gathered to mourn for him; and they buried him at his home in Ramah. Then David set out and went down to the Wilderness of Paran.*
Context
1Samuẹli sì kú; gbogbo ènìyàn Israẹli sì kó ara wọn jọ, wọ́n sì sọkún rẹ̀ wọ́n sì sin ín nínú ilé rẹ̀ ní Rama. Dafidi sì dìde, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ijù Parani. 2Ọkùnrin kan sì ń bẹ ní Maoni, ẹni tí iṣẹ́ rẹ̀ ń bẹ ní Karmeli; ọkùnrin náà sì ní ọrọ̀ púpọ̀, ó sì ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) àgùntàn, àti ẹgbẹ̀rún (1,000) ewúrẹ́: ó sì ń rẹ irun àgùntàn rẹ̀ ní Karmeli. 3Orúkọ ọkùnrin náà sì ń jẹ́ Nabali, orúkọ aya rẹ̀ ń jẹ́ Abigaili; òun sì jẹ́ olóye obìnrin, àti arẹwà ènìyàn; ṣùgbọ́n òǹrorò àti oníwà búburú ni ọkùnrin; ẹni ìdílé Kalebu ni òun jẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.