1 Samuẹli 23:26
1 Samuel 23:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Saulu sì ń rin apá kan òkè kan, Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ní apá kejì òkè náà. Dafidi sì yára láti sá kúrò níwájú Saulu; nítorí pé Saulu àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ti rọ̀gbà yí Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ká láti mú wọn.
1 Samuel 23:26 in English
1 Samuel 23:26 · Berean Standard Bible
Saul was proceeding along one side of the mountain, and David and his men along the other side. Even though David was hurrying to get away, Saul and his men were closing in on David and his men to capture them.
Context
24Wọ́n sì dìde, wọ́n sì ṣáájú Saulu lọ sí Sifi, ṣùgbọ́n Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wà ní aginjù Maoni, ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ níhà gúúsù ti Jeṣimoni. 25Saulu àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì lọ ń wá a. Wọ́n sì sọ fún Dafidi: ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí ibi òkúta kan, ó sì jókòó ní aginjù ti Maoni. Saulu sì gbọ́, ó sì lépa Dafidi ní aginjù Maoni. 26Saulu sì ń rin apá kan òkè kan, Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ní apá kejì òkè náà. Dafidi sì yára láti sá kúrò níwájú Saulu; nítorí pé Saulu àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ti rọ̀gbà yí Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ká láti mú wọn. 27Ṣùgbọ́n oníṣẹ́ kan sì tọ Saulu wá ó sì wí pé, “Ìwọ yára kí o sì wá, nítorí tí àwọn Filistini ti gbé ogun ti ilẹ̀ wa.” 28Saulu sì padà kúrò ní lílépa Dafidi, ó sì lọ pàdé àwọn Filistini nítorí náà ni wọ́n sì ṣe ń pe ibẹ̀ náà ní Selahamalekoti (èyí tí ó túmọ̀ sí “Òkúta Ìpinyà”).
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.