Native Bible

1 Samuel 23:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lọ, èmi bẹ̀ yín, ẹ tún múra, kí ẹ sì mọ̀ ki ẹ si rí ibi tí ẹsẹ̀ rẹ̀ gbé wà, àti ẹni tí ó rí níbẹ̀: nítorí tí a ti sọ fún mi pé, ọgbọ́n ni ó ń lò jọjọ.

1 Samuel 23:22 in English

1 Samuel 23:22 · Berean Standard Bible

Please go and prepare further. Investigate and watch carefully where he goes and who has seen him there, for I am told that he is extremely cunning.

Context

20Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ọba, sọ̀kalẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bi gbogbo ìfẹ́ tí ó wà ní ọkàn rẹ láti sọ̀kalẹ̀: ipa tí àwa ní láti fi lé ọba lọ́wọ́.” 21Saulu sì wí pé, “Alábùkún fún ni ẹ̀yin nípa Olúwa; nítorí pé ẹ̀yin ti káàánú fún mi. 22Lọ, èmi bẹ̀ yín, ẹ tún múra, kí ẹ sì mọ̀ ki ẹ si rí ibi tí ẹsẹ̀ rẹ̀ gbé wà, àti ẹni tí ó rí níbẹ̀: nítorí tí a ti sọ fún mi pé, ọgbọ́n ni ó ń lò jọjọ. 23Ẹ sì wò, kí ẹ sì mọ ibi ìsápamọ́ tí ó máa ń sá pamọ́ sí, kí ẹ sì tún padà tọ̀ mí wá, kí èmi lè mọ̀ dájú; èmi ó sì bá yín lọ: yóò sì ṣe bí ó bá wà ní ilẹ̀ Israẹli, èmi ó sì wá a ní àwárí nínú gbogbo ẹgbẹ̀rún Juda!” 24Wọ́n sì dìde, wọ́n sì ṣáájú Saulu lọ sí Sifi, ṣùgbọ́n Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wà ní aginjù Maoni, ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ níhà gúúsù ti Jeṣimoni.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.