Native Bible

1 Samuel 23:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Dafidi sì wí pé, “Olúwa Ọlọ́run Israẹli, lóòótọ́ ni ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ pé Saulu ń wá ọ̀nà láti wá sí Keila, láti wá fọ́ ìlú náà nítorí mi.

1 Samuel 23:10 in English

1 Samuel 23:10 · Berean Standard Bible

And David said, “O LORD, God of Israel, Your servant has heard that Saul intends to come to Keilah and destroy the city on my account.

Context

8Saulu sì pe gbogbo àwọn ènìyàn náà jọ sí ogun, láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí Keila, láti ká Dafidi mọ́ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀. 9Dafidi sì mọ̀ pé Saulu ti gbèrò búburú sí òun; ó sì wí fún Abiatari àlùfáà náà pé, “Mú efodu náà wá níhìn-ín yìí!” 10Dafidi sì wí pé, “Olúwa Ọlọ́run Israẹli, lóòótọ́ ni ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ pé Saulu ń wá ọ̀nà láti wá sí Keila, láti wá fọ́ ìlú náà nítorí mi. 11Àwọn àgbà ìlú Keila yóò fi mí lé e lọ́wọ́ bí? Saulu yóò ha sọ̀kalẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ bí?” Olúwa Ọlọ́run Israẹli, èmi bẹ̀ ọ́, wí fún ìránṣẹ́ rẹ. Olúwa sì wí pé, “Yóò sọ̀kalẹ̀ wá.” 12Dafidi sì wí pé, “Àwọn àgbà ìlú Keila yóò fi èmi àti àwọn ọmọkùnrin mi lé Saulu lọ́wọ́ bí?” Olúwa sì wí pé, “Wọn ó fi ọ́ lé wọn lọ́wọ́.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.