Native Bible

1 Samuel 22:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Tí gbogbo yín di ìmọ̀lù sí mi, tí kò sì sí ẹnìkan tí ó sọ létí mi pé, ọmọ mi ti bá ọmọ Jese mulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kó sì sí ẹnìkan nínú yín tí ó ṣàánú mi, tí ó sì sọ ọ́ létí mi pé, ọmọ mi mú kí ìránṣẹ́ mi dìde sí mi láti ba dè mí, bí ó ti rí lónìí.”

1 Samuel 22:8 in English

1 Samuel 22:8 · Berean Standard Bible

Is that why all of you have conspired against me? Not one of you told me that my own son had made a covenant with the son of Jesse. Not one of you has shown concern for me or revealed to me that my son has stirred up my own servant to lie in wait against me, as is the case today.”

Context

6Saulu si gbọ́ pé a rí Dafidi àti àwọn ọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀; Saulu sì ń bẹ ní Gibeah lábẹ́ igi tamariski ní Rama; ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀, àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì dúró tì í. 7Nígbà náà ni Saulu wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó dúró tì í, pé, “Ǹjẹ́ ẹ gbọ́ ẹ̀yin ará Benjamini, ọmọ Jese yóò ha fún olúkúlùkù yín ni oko ọgbà àjàrà bí? Kí ó sì sọ gbogbo yin dì olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún bí? 8Tí gbogbo yín di ìmọ̀lù sí mi, tí kò sì sí ẹnìkan tí ó sọ létí mi pé, ọmọ mi ti bá ọmọ Jese mulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kó sì sí ẹnìkan nínú yín tí ó ṣàánú mi, tí ó sì sọ ọ́ létí mi pé, ọmọ mi mú kí ìránṣẹ́ mi dìde sí mi láti ba dè mí, bí ó ti rí lónìí.” 9Doegi ará Edomu tí a fi jẹ olórí àwọn ìránṣẹ́ Saulu, sì dáhùn wí pé, “Èmi rí ọmọ Jese, ó wá sí Nobu, sọ́dọ̀ Ahimeleki ọmọ Ahitubu. 10Òun sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa fún un, ó sì fún un ní oúnjẹ, ó sí fún un ni idà Goliati ará Filistini.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.