1 Samuẹli 22:11
1 Samuel 22:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọba sì ránṣẹ́ pe Ahimeleki àlùfáà, ọmọ Ahitubu àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀, àwọn àlùfáà tí ó wà ni Nobu: gbogbo wọn ni ó sì wá sọ́dọ̀ ọba.
1 Samuel 22:11 in English
1 Samuel 22:11 · Berean Standard Bible
Then the king sent messengers to summon Ahimelech the priest, the son of Ahitub, and his father’s whole family, who were priests at Nob. And all of them came to the king.
Context
9Doegi ará Edomu tí a fi jẹ olórí àwọn ìránṣẹ́ Saulu, sì dáhùn wí pé, “Èmi rí ọmọ Jese, ó wá sí Nobu, sọ́dọ̀ Ahimeleki ọmọ Ahitubu. 10Òun sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa fún un, ó sì fún un ní oúnjẹ, ó sí fún un ni idà Goliati ará Filistini.” 11Ọba sì ránṣẹ́ pe Ahimeleki àlùfáà, ọmọ Ahitubu àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀, àwọn àlùfáà tí ó wà ni Nobu: gbogbo wọn ni ó sì wá sọ́dọ̀ ọba. 12Saulu sì wí pé, “Ǹjẹ́ gbọ́, ìwọ ọmọ Ahitubu.”
Òun sì wí pé, “Èmi nìyìí olúwa mi.” 13Saulu sì wí fún un pé, “Kí ni ó dé tí ẹ̀yin fi ṣọ̀tẹ̀ sí mi, ìwọ àti ọmọ Jese, tí ìwọ fi fún un ní àkàrà, àti idà, àti ti ìwọ fi béèrè fún un lọ́dọ̀ Ọlọ́run kí òun lè dìde sí mi, láti ba dè mí, bí ó ti rí lónìí.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.