Native Bible

1 Samuel 20:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí ó bá sì ṣe pé baba rẹ bá fẹ́ mi kù, kí o sì wí fún un pé, ‘Dafidi fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ béèrè ààyè láti sáré lọ sí Bẹtilẹhẹmu ìlú rẹ̀ nítorí wọ́n ń ṣe ẹbọ ọdọọdún ní ibẹ̀ fún gbogbo ìdílé rẹ̀.’

1 Samuel 20:6 in English

1 Samuel 20:6 · Berean Standard Bible

If your father misses me at all, tell him, ‘David urgently requested my permission to hurry to Bethlehem, his hometown, because there is an annual sacrifice for his whole clan.’

Context

4Jonatani wí fún Dafidi pé, “Ohunkóhun tí ìwọ bá ń fẹ́ kí èmi kí ó ṣe, èmi yóò ṣe é fún ọ.” 5Dafidi sì wí fún Jonatani pé, “Wò ó, ọ̀la ni oṣù tuntun, mo sì gbọdọ̀ bá ọba jẹun, ṣùgbọ́n jẹ́ kí èmi kí ó lọ láti fi ara pamọ́ lórí pápá títí di àṣálẹ́ ọjọ́ kẹta. 6Bí ó bá sì ṣe pé baba rẹ bá fẹ́ mi kù, kí o sì wí fún un pé, ‘Dafidi fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ béèrè ààyè láti sáré lọ sí Bẹtilẹhẹmu ìlú rẹ̀ nítorí wọ́n ń ṣe ẹbọ ọdọọdún ní ibẹ̀ fún gbogbo ìdílé rẹ̀.’ 7Tí o bá wí pé, ‘Àlàáfíà ni,’ nígbà náà, ìránṣẹ́ rẹ wà láìléwu. Ṣùgbọ́n tí ó bá bínú gidigidi, ìwọ yóò mọ̀ dájú pé ó pinnu láti ṣe ìpalára mi. 8Ṣùgbọ́n ní tìrẹ ìwọ, fi ojúrere wo ìránṣẹ́ rẹ; nítorí tí ìwọ ti bá a dá májẹ̀mú pẹ̀lú rẹ níwájú Olúwa. Tí mo bá jẹ̀bi, pa mí fún ara rẹ! Èéṣe tí ìwọ yóò fi fi mí lé baba rẹ lọ́wọ́?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.