1 Samuẹli 20:21
1 Samuel 20:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò rán ọmọdékùnrin kan èmi yóò wí fún un wí pé, ‘Lọ, kí o lọ wá ọfà náà.’ Tí mo bá sọ fún un wí pé, ‘Wò ó, ọfà wọ̀nyí wà ní ibi báyìí ní ẹ̀gbẹ́ ẹ̀ rẹ; kó wọn wá síbí,’ kí o sì wá, nítorí pé, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wà ní ààyè, o wà ní àlàáfíà; kò sí ewu.
1 Samuel 20:21 in English
1 Samuel 20:21 · Berean Standard Bible
Then I will send a boy and say, ‘Go, find the arrows!’ Now, if I expressly say to him, ‘Look, the arrows are on this side of you; bring them,’ then come, because as surely as the LORD lives, it is safe for you and there is no danger.
Context
19Ní ọ̀túnla lọ́wọ́ alẹ́ lọ sí ibi tí o sá pamọ́ sí nígbà tí ìṣòro yìí bẹ̀rẹ̀, kí o sì dúró níbi òkúta Eselu. 20Èmi yóò ta ọfà mẹ́ta sí ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀, gẹ́gẹ́ bí i pé mo ta á sí àmì ibìkan. 21Èmi yóò rán ọmọdékùnrin kan èmi yóò wí fún un wí pé, ‘Lọ, kí o lọ wá ọfà náà.’ Tí mo bá sọ fún un wí pé, ‘Wò ó, ọfà wọ̀nyí wà ní ibi báyìí ní ẹ̀gbẹ́ ẹ̀ rẹ; kó wọn wá síbí,’ kí o sì wá, nítorí pé, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wà ní ààyè, o wà ní àlàáfíà; kò sí ewu. 22Ṣùgbọ́n tí mo bá sọ fún ọmọdékùnrin náà pé, ‘Wò ó, àwọn ọfà náà ń bẹ níwájú rẹ,’ ǹjẹ́ máa bá tìrẹ lọ, nítorí Olúwa ni ó rán ọ lọ. 23Nípa ọ̀rọ̀ tí èmi àti ìwọ jọ sọ, rántí Olúwa jẹ́ ẹlẹ́rìí láàrín ìwọ àti èmi títí láéláé.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.