1 Samuẹli 2:30
1 Samuel 2:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Nítorí náà Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí pé, ‘Èmi ti wí nítòótọ́ pé, ilé rẹ àti ilé baba rẹ, yóò máa rìn níwájú mi títí.’ Ṣùgbọ́n nísinsin yìí Olúwa wí pé, ‘Kí á má rí i! Àwọn tí ó bú ọlá fún mi ni èmi yóò bu ọlá fún, àti àwọn tí kò kà mí sí ni a ó sì ṣe aláìkàsí.
1 Samuel 2:30 in English
1 Samuel 2:30 · Berean Standard Bible
Therefore, the LORD, the God of Israel, declares: ‘I did indeed say that your house and the house of your father would walk before Me forever. But now the LORD declares: Far be it from Me! For I will honor those who honor Me, but those who despise Me will be disdained.
Context
28Èmi sì yàn án kúrò láàrín gbogbo ẹ̀yà Israẹli láti jẹ́ àlùfáà mi, láti rú ẹbọ lórí pẹpẹ mi, láti fi tùràrí jóná, láti wọ efodu níwájú mi, èmi sì fi gbogbo ẹbọ tí ọmọ Israẹli máa ń fi iná sun fún ìdílé baba rẹ̀. 29Èéha ṣe tí ẹ̀yin fi tàpá sí ẹbọ àti ọrẹ mi, tí mo pàṣẹ ní ibùjókòó mi, ìwọ sì bu ọlá fún àwọn ọmọ rẹ jù mí lọ, tí ẹ sì fi gbogbo àṣàyàn ẹbọ Israẹli àwọn ènìyàn mi mú ara yín sanra.’ 30“Nítorí náà Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí pé, ‘Èmi ti wí nítòótọ́ pé, ilé rẹ àti ilé baba rẹ, yóò máa rìn níwájú mi títí.’ Ṣùgbọ́n nísinsin yìí Olúwa wí pé, ‘Kí á má rí i! Àwọn tí ó bú ọlá fún mi ni èmi yóò bu ọlá fún, àti àwọn tí kò kà mí sí ni a ó sì ṣe aláìkàsí. 31Kíyèsi i, àwọn ọjọ́ ń bọ̀ tí èmi ó gé agbára rẹ kúrò, àti agbára baba rẹ, tí kì yóò sí arúgbó kan nínú ilé rẹ. 32Ìwọ yóò rí wàhálà ti Àgọ́, nínú gbogbo ọlá tí Ọlọ́run yóò fi fún Israẹli; kì yóò sí arúgbó kan nínú ilé rẹ láéláé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.