Native Bible

1 Samuel 19:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá sí orí Saulu bí ó ti jókòó ní ilé e rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀. Bí Dafidi sì ti fọn ohun èlò orin olókùn,

1 Samuel 19:9 in English

1 Samuel 19:9 · Berean Standard Bible

But as Saul was sitting in his house with his spear in his hand, a spirit of distress * from the LORD came upon him. While David was playing the harp,

Context

7Nítorí náà Jonatani pe Dafidi, ó sì sọ gbogbo àjọsọ wọn fún un. Ó sì mú un wá fún Saulu, Dafidi sì wà lọ́dọ̀ Saulu gẹ́gẹ́ bí i ti tẹ́lẹ̀. 8Lẹ́ẹ̀kan an sí i ogun tún wá, Dafidi sì jáde lọ, ó sì bá àwọn ara Filistini jà. Ó sì pa wọn pẹ̀lú agbára, wọ́n sì sálọ níwájú u rẹ̀. 9Ṣùgbọ́n ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá sí orí Saulu bí ó ti jókòó ní ilé e rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀. Bí Dafidi sì ti fọn ohun èlò orin olókùn, 10Saulu sì wá ọ̀nà láti gún un mọ́ ògiri pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n Dafidi yẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Saulu ti ju ọ̀kọ̀ náà mọ́ ara ògiri. Ní alẹ́ ọjọ́ náà Dafidi sì fi ara pamọ́ dáradára. 11Saulu rán ènìyàn sí ilé Dafidi láti ṣọ́ ọ kí wọ́n sì pa á ní òwúrọ̀. Ṣùgbọ́n Mikali, ìyàwó Dafidi kìlọ̀ fún un pé, “Tí o kò bá sá fún ẹ̀mí rẹ ní alẹ́ yìí, ní ọ̀la ni a yóò pa ọ́.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.