1 Samuẹli 19:17
1 Samuel 19:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Saulu wí fún Mikali pé, “Èéṣe tí ìwọ fi tàn mí báyìí tí o sì jẹ́ kí ọ̀tá mi sálọ tí ó sì bọ́?” Mikali sọ fún un pé, “Ó wí fún mi, ‘Jẹ́ kí èmi ó lọ. Èéṣe tí èmi yóò fi pa ọ́?’ ”
1 Samuel 19:17 in English
1 Samuel 19:17 · Berean Standard Bible
And Saul said to Michal, “Why did you deceive me like this? You sent my enemy away and he has escaped!” Michal replied, “He said to me, ‘Help me get away, or I will kill you!’”
Context
15Nígbà náà ni Saulu rán ọkùnrin náà padà láti lọ wo Dafidi ó sì sọ fún wọn pé, “Mú wa fún mi láti orí ibùsùn rẹ̀ kí èmi kí ó le pa á.” 16Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkùnrin náà wọlé, ère ni ó bá lórí ibùsùn àti irun ewúrẹ́ ní orí ère náà. 17Saulu wí fún Mikali pé, “Èéṣe tí ìwọ fi tàn mí báyìí tí o sì jẹ́ kí ọ̀tá mi sálọ tí ó sì bọ́?”
Mikali sọ fún un pé, “Ó wí fún mi, ‘Jẹ́ kí èmi ó lọ. Èéṣe tí èmi yóò fi pa ọ́?’ ” 18Nígbà tí Dafidi ti sálọ tí ó sì ti bọ́, ó sì lọ sọ́dọ̀ Samuẹli ní Rama ó sì sọ gbogbo ohun tí Saulu ti ṣe fún un. Òun àti Samuẹli lọ sí Naioti láti dúró níbẹ̀. 19Ọ̀rọ̀ sì tọ Saulu wá pé, “Dafidi wà ní Naioti ní Rama,”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.