1 Samuẹli 18:28
1 Samuel 18:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí Saulu sì wá mọ̀ pé Olúwa wà pẹ̀lú Dafidi tí ọmọbìnrin rẹ̀ Mikali sì fẹ́ràn Dafidi,
1 Samuel 18:28 in English
1 Samuel 18:28 · Berean Standard Bible
When Saul realized that the LORD was with David and that his daughter Michal loved David,
Context
26Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ sọ àwọn nǹkan yìí fún Dafidi, inú rẹ̀ dùn láti di àna ọba kí àkókò tí ó dá tó kọjá, 27Dafidi àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jáde lọ wọ́n sì pa igba lára àwọn Filistini. Ó kó awọ iwájú orí wọn wá, ó sì pé iye tí ọba fẹ́ kí ó ba à lè jẹ́ àna ọba. Saulu sì fi ọmọ obìnrin Mikali fún un ní aya. 28Nígbà tí Saulu sì wá mọ̀ pé Olúwa wà pẹ̀lú Dafidi tí ọmọbìnrin rẹ̀ Mikali sì fẹ́ràn Dafidi, 29Saulu sì tún wá bẹ̀rù Dafidi síwájú àti síwájú, Saulu sì wá di ọ̀tá Dafidi fún gbogbo ọjọ́ rẹ̀ tókù. 30Àwọn ọmọ-aládé Filistini tún tẹ̀síwájú láti lọ sí ogun, ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n lọ, Dafidi ṣe àṣeyọrí ju gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Saulu lọ, orúkọ rẹ̀ sì gbilẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.