1 Samuẹli 18:17
1 Samuel 18:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Saulu wí fún Dafidi pé, “Èyí ni àgbà nínú àwọn ọmọbìnrin mi Merabu. Èmi yóò fi òun fún ọ ní aya. Kí ìwọ sìn mí bí akọni, kí o sì máa ja ogun Olúwa.” Nítorí tí Saulu wí fún ara rẹ̀ pé, “Èmi kì yóò gbé ọwọ́ mi sókè sí i. Jẹ́ kí àwọn Filistini ṣe èyí.”
1 Samuel 18:17 in English
1 Samuel 18:17 · Berean Standard Bible
Then Saul said to David, “Here is my older daughter Merab. I will give her to you in marriage. Only be valiant for me and fight the LORD’s battles.” But Saul was thinking, “I need not raise my hand against him; let the hand of the Philistines be against him.”
Context
15Nígbà tí Saulu rí bi àṣeyọrí rẹ̀ ti tó, ó sì bẹ̀rù rẹ̀. 16Ṣùgbọ́n gbogbo Israẹli àti Juda ni wọ́n fẹ́ràn Dafidi, nítorí ó darí wọn lọ ní ìgbòkègbodò ogun wọn. 17Saulu wí fún Dafidi pé, “Èyí ni àgbà nínú àwọn ọmọbìnrin mi Merabu. Èmi yóò fi òun fún ọ ní aya. Kí ìwọ sìn mí bí akọni, kí o sì máa ja ogun Olúwa.” Nítorí tí Saulu wí fún ara rẹ̀ pé, “Èmi kì yóò gbé ọwọ́ mi sókè sí i. Jẹ́ kí àwọn Filistini ṣe èyí.” 18Ṣùgbọ́n Dafidi wí fún Saulu pé, “Ta ni mí, kí sì ni ìdílé mi tàbí ìdílé baba mi ní Israẹli, tí èmi yóò di àna ọba?” 19Nígbà tí àkókò tó fún Merabu, ọmọbìnrin Saulu, láti fi fún Dafidi, ni a sì fi fún Adrieli ará Mehola ní aya.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.