1 Samuẹli 17:46
1 Samuel 17:46 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lónìí yìí ni Olúwa yóò fi ọ́ lé mi lọ́wọ́, èmi yóò sì pa ọ́, èmi yóò sì gé orí rẹ. Lónìí èmi yóò fi òkú ogun Filistini fún ẹyẹ ojú ọ̀run àti fún ẹranko igbó, gbogbo ayé yóò sì mọ̀ pé Ọlọ́run wà ní Israẹli.
1 Samuel 17:46 in English
1 Samuel 17:46 · Berean Standard Bible
This day the LORD will deliver you into my hand. This day I will strike you down, cut off your head, and give the carcasses of the Philistines to the birds of the air and the creatures of the earth. Then the whole world will know that there is a God in Israel.
Context
44Filistini náà sì wí Dafidi pé, “Wá níbí, èmi yóò fi ẹran-ara rẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run jẹ àti fún àwọn ẹranko tí ó wà nínú igbó!” 45Dafidi sì wí fún Filistini pé, “Ìwọ dojú ìjà kọ mí pẹ̀lú idà, ọ̀kọ̀ àti ọfà, ṣùgbọ́n èmi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ pẹ̀lú orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Israẹli tí ìwọ tí gàn. 46Lónìí yìí ni Olúwa yóò fi ọ́ lé mi lọ́wọ́, èmi yóò sì pa ọ́, èmi yóò sì gé orí rẹ. Lónìí èmi yóò fi òkú ogun Filistini fún ẹyẹ ojú ọ̀run àti fún ẹranko igbó, gbogbo ayé yóò sì mọ̀ pé Ọlọ́run wà ní Israẹli. 47Gbogbo àwọn tí ó péjọ níbí ni yóò mọ̀ pé kì í ṣe nípa ọ̀kọ̀ tàbí idà ni Olúwa fi ń gbàlà; ogun náà ti Olúwa ni, yóò sì fi gbogbo yín lé ọwọ́ wa.” 48Bí Filistini ṣe súnmọ́ iwájú láti pàdé e rẹ̀. Dafidi yára sáré sí òun náà láti pàdé e rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.