1 Samuẹli 17:39
1 Samuel 17:39 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Dafidi si di idà rẹ̀ mọ́ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní rìn káàkiri nítorí wí pé kò mọ́ ọ lára. Ó sọ fún Saulu pé, “Èmi kò le wọ èyí lọ, kò mọ́ mi lára.” Ó sì bọ́ wọn kúrò.
1 Samuel 17:39 in English
1 Samuel 17:39 · Berean Standard Bible
David strapped his sword over the tunic and tried to walk, but he was not accustomed to them. “I cannot walk in these,” David said to Saul. “I am not accustomed to them.” So David took them off.
Context
37Olúwa tí ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìhàlẹ̀ kìnnìún àti ti ìhàlẹ̀ àmọ̀tẹ́kùn yóò gbà mí kúrò lọ́wọ́ Filistini yìí.”
Saulu wí fún Dafidi pé, “Lọ kí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.” 38Saulu fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ wọ Dafidi, ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ ìhámọ́ra ogun, ó sì fi ìbòrí idẹ kan bò ó ní orí. 39Dafidi si di idà rẹ̀ mọ́ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní rìn káàkiri nítorí wí pé kò mọ́ ọ lára.
Ó sọ fún Saulu pé, “Èmi kò le wọ èyí lọ, kò mọ́ mi lára.” Ó sì bọ́ wọn kúrò. 40Nígbà náà, ó sì mú ọ̀pá rẹ̀ lọ́wọ́, ó ṣá òkúta dídán márùn-ún létí odò, ó kó wọn sí àpò olùṣọ́-àgùntàn tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀ pẹ̀lú kànnàkànnà, ó sì súnmọ́ Filistini náà. 41Lákòókò yìí, Filistini pẹ̀lú ẹni tí ń gbé ìhámọ́ra ààbò wà níwájú rẹ̀, ó ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ Dafidi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.