1 Samuẹli 17:11
1 Samuel 17:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí Saulu àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ ọ̀rọ̀ Filistini, ìdààmú bá wọn.
1 Samuel 17:11 in English
1 Samuel 17:11 · Berean Standard Bible
On hearing the words of the Philistine, Saul and all the Israelites were dismayed and greatly afraid.
Context
9Tí òhun bá sì le jà tí ó sì pa mí, àwa yóò di ẹrú u yín, ṣùgbọ́n tí èmi bá lè ṣẹ́gun rẹ̀ tí mo sì pa á, ẹ̀yin yóò di ẹrú u wa, ẹ̀yin yóò sì máa sìn wá.” 10Nígbà náà Filistini náà wí pé, “Èmi fi ìjà lọ ogun Israẹli ní òní! Ẹ mú ọkùnrin kan wá kí ẹ sì jẹ́ kí a bá ara wa jà.” 11Nígbà tí Saulu àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ ọ̀rọ̀ Filistini, ìdààmú bá wọn. 12Nísinsin yìí Dafidi jẹ́ ọmọ ará Efrata kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jese, tí ó wá láti Bẹtilẹhẹmu ní Juda, Jese ní ọmọ mẹ́jọ, ní àsìkò Saulu ó ti darúgbó ẹni ọdún púpọ̀. 13Àwọn ọmọ Jese mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ó ti dàgbà bá Saulu lọ sí ojú ogun, èyí àkọ́bí ni Eliabu, èyí èkejì ni Abinadabu, èyí ẹ̀kẹta sì ní Ṣamma.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.