1 Samuẹli 16:5
1 Samuel 16:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Samuẹli sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni àlàáfíà ni; mo wá láti wá rú ẹbọ sí Olúwa. Ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì wá rú ẹbọ pẹ̀lú mi.” Nígbà náà ni ó sì ya Jese sí mímọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì pè wọ́n wá sí ibi ìrúbọ náà.
1 Samuel 16:5 in English
1 Samuel 16:5 · Berean Standard Bible
“In peace,” he replied. “I have come to sacrifice to the LORD. Consecrate yourselves and come with me to the sacrifice.” Then he consecrated Jesse and his sons and invited them to the sacrifice.
Context
3Pe Jese wá sí ibi ìrúbọ náà, Èmi yóò sì fi ohun tí ìwọ yóò ṣe hàn ọ́. Ìwọ yóò fi òróró yàn fún mi, ẹni tí èmi bá fihàn ọ́.” 4Samuẹli ṣe ohun tí Olúwa sọ. Nígbà tí ó dé Bẹtilẹhẹmu, àyà gbogbo àgbàgbà ìlú já, nígbà tí wọ́n pàdé rẹ̀. Wọ́n béèrè pé, “Ṣé àlàáfíà ní ìwọ bá wá?” 5Samuẹli sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni àlàáfíà ni; mo wá láti wá rú ẹbọ sí Olúwa. Ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì wá rú ẹbọ pẹ̀lú mi.” Nígbà náà ni ó sì ya Jese sí mímọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì pè wọ́n wá sí ibi ìrúbọ náà. 6Nígbà tí wọ́n dé, Samuẹli rí Eliabu, ó rò nínú ara rẹ̀ pé lóòótọ́ ẹni òróró Olúwa dúró níbí níwájú Olúwa. 7Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún Samuẹli pé, “Má ṣe wo ti ìrísí rẹ̀ tàbí ti gíga rẹ̀, nítorí èmi ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Olúwa kì í wo ohun tí ènìyàn máa ń wò. Ènìyàn máa ń wo òde ara ṣùgbọ́n Olúwa máa ń wo ọkàn.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.