Native Bible

1 Samuel 16:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọ̀kan nínú ìránṣẹ́ náà dáhùn pé, “Èmi ti ri ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Jese ti Bẹtilẹhẹmu tí ó mọ orin kọ, ó jẹ́ alágbára àti ológun. Ó ní ọgbọ́n ọ̀rọ̀ òun sì dára ní wíwò. Olúwa sì wà pẹ̀lú u rẹ̀.”

1 Samuel 16:18 in English

1 Samuel 16:18 · Berean Standard Bible

One of the servants answered, “I have seen a son of Jesse of Bethlehem who knows how to play the harp. He is a mighty man of valor, a warrior, eloquent and handsome, and the LORD is with him.”

Context

16Jẹ́ kí olúwa wa pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó wà níhìn-ín láti wa ẹnìkan tí ó lè fi dùùrù kọrin. Yóò sì ṣe é nígbà tí ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bá bà lé ọ, ìwọ yóò sì sàn.” 17Nígbà náà ni Saulu wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ wá ẹnìkan tí ó lè kọrin dáradára kí ẹ sì mú u wá fún mi.” 18Ọ̀kan nínú ìránṣẹ́ náà dáhùn pé, “Èmi ti ri ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Jese ti Bẹtilẹhẹmu tí ó mọ orin kọ, ó jẹ́ alágbára àti ológun. Ó ní ọgbọ́n ọ̀rọ̀ òun sì dára ní wíwò. Olúwa sì wà pẹ̀lú u rẹ̀.” 19Saulu sì rán oníṣẹ́ sí Jese wí pé, “Rán Dafidi ọmọ rẹ sí mi, ẹni tí ó ń ṣọ́ àgùntàn.” 20Jese sì mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ti a di ẹrù lé àti ìgò ọtí wáìnì àti ọmọ ewúrẹ́; ó sì rán wọn nípa ọwọ́ Dafidi ọmọ rẹ̀ sí Saulu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.