Native Bible

1 Samuel 16:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ìránṣẹ́ Saulu sì wí fún un pé, “Wò ó, ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ń yọ ọ́ lẹ́nu.

1 Samuel 16:15 in English

1 Samuel 16:15 · Berean Standard Bible

Saul’s servants said to him, “Surely a spirit of distress from God is tormenting you.

Context

13Nígbà náà ni Samuẹli mú ìwo òróró, ó sì ta á sí i ní orí ní iwájú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀, láti ọjọ́ náà lọ, Ẹ̀mí Mímọ́ Olúwa wá sí orí Dafidi nínú agbára. Samuẹli sì lọ sí Rama. 14Nísinsin yìí, ẹ̀mí Olúwa ti kúrò lára Saulu, ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Olúwa sì ń yọ ọ́ lẹ́nu. 15Àwọn ìránṣẹ́ Saulu sì wí fún un pé, “Wò ó, ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ń yọ ọ́ lẹ́nu. 16Jẹ́ kí olúwa wa pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó wà níhìn-ín láti wa ẹnìkan tí ó lè fi dùùrù kọrin. Yóò sì ṣe é nígbà tí ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bá bà lé ọ, ìwọ yóò sì sàn.” 17Nígbà náà ni Saulu wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ wá ẹnìkan tí ó lè kọrin dáradára kí ẹ sì mú u wá fún mi.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.