1 Samuẹli 15:10
1 Samuel 15:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Samuẹli wá pé,
1 Samuel 15:10 in English
1 Samuel 15:10 · Berean Standard Bible
Then the word of the LORD came to Samuel, saying,
Context
8Ó sì mú Agagi ọba Amaleki láààyè, ó sì fi idà rẹ̀ kọlù gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀. 9Ṣùgbọ́n Saulu àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ dá Agagi sí àti èyí tí ó dára jùlọ nínú àgùntàn àti màlúù àti ọ̀dọ́-àgùntàn àbọ́pa àti gbogbo nǹkan tó dára. Wọ́n kò sì fẹ́ pa àwọn wọ̀nyí run pátápátá ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan tí kò dára tí kò sì níláárí ni wọ́n parun pátápátá. 10Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Samuẹli wá pé, 11“Èmi káàánú gidigidi pé mo fi Saulu jẹ ọba, nítorí pé ó ti yípadà kúrò lẹ́yìn mi, kò sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́.” Inú Samuẹli sì bàjẹ́ gidigidi, ó sì ké pe Olúwa ní gbogbo òru náà. 12Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù Samuẹli sì dìde láti lọ pàdé Saulu, ṣùgbọ́n wọ́n sọ fún un pé, “Saulu ti wá sí Karmeli. Ó ti kọ́ ibìkan fún ara rẹ̀ níbẹ̀, ó sì ti yípadà, ó sì ti sọ̀kalẹ̀ lọ sí Gilgali.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.