Native Bible

1 Samuel 14:34 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni ó wí pé, “Ẹ jáde lọ sáàrín àwọn ènìyàn náà kí ẹ sì wí fún wọn pé, ‘Kí olúkúlùkù wọn mú màlúù àti àgùntàn tirẹ̀ tọ̀ mí wá, kí wọ́n sì pa wọ́n níhìn-ín, kí wọ́n sì jẹ́. Ẹ má ṣe ṣẹ̀ sí Olúwa, kí ẹ má ṣe jẹ ẹran tòun-tẹ̀jẹ̀.’ ” Bẹ́ẹ̀ ní olúkúlùkù mú màlúù tirẹ̀ wá ní alẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n sì pa wọ́n níbẹ̀.

1 Samuel 14:34 in English

1 Samuel 14:34 · Berean Standard Bible

Then he said, “Go among the troops and tell them, ‘Each man must bring me his ox or his sheep, slaughter them in this place, and then eat. Do not sin against the LORD by eating meat with the blood still in it.’” So that night everyone brought his ox and slaughtered it there.

Context

32Wọ́n sáré sí ìkógun náà, wọ́n sì mú àgùntàn. Màlúù àti ọmọ màlúù, wọ́n pa wọ́n sórí ilẹ̀, wọ́n sì jẹ wọ́n papọ̀ tẹ̀jẹ́tẹ̀jẹ̀. 33Nígbà náà ni ẹnìkan sì wí fún Saulu pé, “Wò ó, àwọn ènìyàn tí ń dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa nípa jíjẹ ẹran tí ó ní ẹ̀jẹ̀ lára.” Ó sì wí pé, “Ẹ̀ṣẹ̀ yín ti pọ̀jù, yí òkúta ńlá sí ibi nísinsin yìí.” 34Nígbà náà ni ó wí pé, “Ẹ jáde lọ sáàrín àwọn ènìyàn náà kí ẹ sì wí fún wọn pé, ‘Kí olúkúlùkù wọn mú màlúù àti àgùntàn tirẹ̀ tọ̀ mí wá, kí wọ́n sì pa wọ́n níhìn-ín, kí wọ́n sì jẹ́. Ẹ má ṣe ṣẹ̀ sí Olúwa, kí ẹ má ṣe jẹ ẹran tòun-tẹ̀jẹ̀.’ ” Bẹ́ẹ̀ ní olúkúlùkù mú màlúù tirẹ̀ wá ní alẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n sì pa wọ́n níbẹ̀. 35Nígbà náà Saulu kọ́ pẹpẹ kan fún Olúwa; èyí sì jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ ṣe èyí. 36Saulu sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sọ̀kalẹ̀ tọ Filistini lọ ní òru, kí a bá wọn jà títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀, kí a má ṣì ṣe dá ẹnìkankan sí nínú wọn.” Wọ́n sì wí pé, “Ṣe ohun tí ó bá dára ní ojú rẹ̀.” Ṣùgbọ́n àlùfáà wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Ọlọ́run níhìn-ín.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.