Native Bible

1 Samuel 14:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọjọ́ náà, lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ọmọ Israẹli ti pa nínú àwọn Filistini láti Mikmasi dé Aijaloni, ó sì rẹ àwọn ènìyàn náà.

1 Samuel 14:31 in English

1 Samuel 14:31 · Berean Standard Bible

That day, after the Israelites had struck down the Philistines from Michmash to Aijalon, the people were very faint.

Context

29Jonatani sì wí pé, “Baba mi ti mú ìdààmú bá ìlú, wò ó bí ojú mi ti dán nígbà tí mo fi ẹnu kan oyin yìí. 30Báwo ni kò bá ti dára tó bí àwọn ènìyàn bá ti jẹ nínú ìkógun àwọn ọ̀tá wọn lónìí, pípa àwọn Filistini ìbá ti pọ̀ tó?” 31Ní ọjọ́ náà, lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ọmọ Israẹli ti pa nínú àwọn Filistini láti Mikmasi dé Aijaloni, ó sì rẹ àwọn ènìyàn náà. 32Wọ́n sáré sí ìkógun náà, wọ́n sì mú àgùntàn. Màlúù àti ọmọ màlúù, wọ́n pa wọ́n sórí ilẹ̀, wọ́n sì jẹ wọ́n papọ̀ tẹ̀jẹ́tẹ̀jẹ̀. 33Nígbà náà ni ẹnìkan sì wí fún Saulu pé, “Wò ó, àwọn ènìyàn tí ń dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa nípa jíjẹ ẹran tí ó ní ẹ̀jẹ̀ lára.” Ó sì wí pé, “Ẹ̀ṣẹ̀ yín ti pọ̀jù, yí òkúta ńlá sí ibi nísinsin yìí.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.