1 Samuẹli 14:13
1 Samuel 14:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jonatani lo ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ láti fà gòkè pẹ̀lú ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àwọn Filistini sì ṣubú níwájú Jonatani ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ sì tẹ̀lé e, ó sì ń pa lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.
1 Samuel 14:13 in English
1 Samuel 14:13 · Berean Standard Bible
So Jonathan climbed up on his hands and feet, with his armor-bearer behind him. And the Philistines fell before Jonathan, and his armor-bearer followed and finished them off.
Context
11Báyìí ní àwọn méjèèjì sì fi ara wọn hàn fún ìlú olódi Filistini. Àwọn Filistini sì wí pé, “Wò ó! Àwọn Heberu ń yọ jáde wá láti inú ihò tí wọ́n fi ara wọn pamọ́ sí.” 12Àwọn ọkùnrin ìlú olódi náà sì kígbe sí Jonatani àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Ẹ gòkè tọ̀ wá wá àwa yóò sì kọ́ ọ yín ní ẹ̀kọ́.”
Jonatani sì wí fún ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Gòkè tọ̀ mí lẹ́yìn; Olúwa ti fi wọ́n lé Israẹli lọ́wọ́.” 13Jonatani lo ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ láti fà gòkè pẹ̀lú ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àwọn Filistini sì ṣubú níwájú Jonatani ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ sì tẹ̀lé e, ó sì ń pa lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. 14Ní ìkọlù èkínní yìí, Jonatani àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ sì pa ogún ọkùnrin ní agbègbè tó tó ìwọ̀n ààbọ̀ sáré ilẹ̀. 15Nígbà náà ni ìbẹ̀rùbojo bá àwọn ọmọ-ogun; àwọn tí ó wà ní ibùdó àti ní pápá, àti àwọn tí ó wà ní ilé ìlú olódi àti àwọn tí ń kó ìkógun, ilẹ̀ sì mì. Ó jẹ́ ìbẹ̀rù tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.