1 Samuẹli 14:10
1 Samuel 14:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá wí pé, ‘Ẹ gòkè tọ̀ wá wá,’ àwa yóò gòkè lọ, nítorí èyí ni yóò jẹ́ àmì fún wa pé Olúwa ti fi wọ́n lé wa lọ́wọ́.”
1 Samuel 14:10 in English
1 Samuel 14:10 · Berean Standard Bible
But if they say, ‘Come on up,’ then we will go up, because this will be our sign that the LORD has delivered them into our hands.”
Context
8Jonatani sì wí pé, “Wá nígbà náà, àwa yóò rékọjá sí ọ̀dọ̀ ọkùnrin wọ̀nyí, kí a sì jẹ́ kí wọ́n rí wa. 9Bí wọ́n bá sọ fún wa pé, ‘Ẹ dúró títí àwa yóò fi tọ̀ yín wá,’ àwa yóò dúró sí ibi tí a wà, àwa kì yóò sì gòkè tọ̀ wọ́n lọ. 10Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá wí pé, ‘Ẹ gòkè tọ̀ wá wá,’ àwa yóò gòkè lọ, nítorí èyí ni yóò jẹ́ àmì fún wa pé Olúwa ti fi wọ́n lé wa lọ́wọ́.” 11Báyìí ní àwọn méjèèjì sì fi ara wọn hàn fún ìlú olódi Filistini. Àwọn Filistini sì wí pé, “Wò ó! Àwọn Heberu ń yọ jáde wá láti inú ihò tí wọ́n fi ara wọn pamọ́ sí.” 12Àwọn ọkùnrin ìlú olódi náà sì kígbe sí Jonatani àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Ẹ gòkè tọ̀ wá wá àwa yóò sì kọ́ ọ yín ní ẹ̀kọ́.”
Jonatani sì wí fún ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Gòkè tọ̀ mí lẹ́yìn; Olúwa ti fi wọ́n lé Israẹli lọ́wọ́.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.