1 Samuẹli 14:1
1 Samuel 14:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ọjọ́ kan, Jonatani ọmọ Saulu wí fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó ń ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Wá, jẹ́ kí a rékọjá lọ sí ìlú olódi àwọn Filistini tí ó wà ní ìhà kejì.” Ṣùgbọ́n kò sọ fún baba rẹ̀.
1 Samuel 14:1 in English
1 Samuel 14:1 · Berean Standard Bible
One day Jonathan son of Saul said to the young man bearing his armor, “Come, let us cross over to the Philistine outpost on the other side.” But Jonathan did not tell his father.
Context
1Ní ọjọ́ kan, Jonatani ọmọ Saulu wí fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó ń ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Wá, jẹ́ kí a rékọjá lọ sí ìlú olódi àwọn Filistini tí ó wà ní ìhà kejì.” Ṣùgbọ́n kò sọ fún baba rẹ̀. 2Saulu sì dúró ní ìhà etí ìpínlẹ̀ Gibeah lábẹ́ igi pomegiranate èyí tí ó wà ní Migroni. Àwọn ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin sì wà pẹ̀lú rẹ̀, 3lára wọn ni Ahijah, tí ó wọ efodu. Òun ni ọmọ arákùnrin Ikabodu Ahitubu, ọmọ Finehasi, ọmọ Eli, àlùfáà Olúwa ní Ṣilo kò sí ẹni tí ó mọ̀ pé Jonatani ti lọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.