1 Samuẹli 13:5
1 Samuel 13:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn Filistini kó ara wọn jọ pọ̀ láti bá Israẹli jà, pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) kẹ̀kẹ́, ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ọkùnrin ẹlẹ́ṣin, àwọn ológun sì pọ̀ bí yanrìn etí Òkun. Wọ́n sì gòkè lọ, wọ́n dó ní Mikmasi ní ìhà ilẹ̀ oòrùn Beti-Afeni.
1 Samuel 13:5 in English
1 Samuel 13:5 · Berean Standard Bible
Now the Philistines assembled to fight against Israel with three thousand * chariots, six thousand horsemen, and troops as numerous as the sand on the seashore. They went up and camped at Michmash, east of Beth-aven.
Context
3Jonatani sì kọlu ẹgbẹ́ ogun àwọn Filistini ní Gibeah, Filistini sì gbọ́ èyí. Nígbà náà ni Saulu fọn ìpè yí gbogbo ilẹ̀ náà ká, ó sì wí pé, “Jẹ́ kí àwọn Heberu gbọ́!” 4Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Israẹli sì gbọ́ ìròyìn pé, “Saulu ti kọlu ẹgbẹ́ ogun àwọn Filistini, Israẹli sì di òórùn búburú fún àwọn Filistini.” Àwọn ènìyàn náà sì péjọ láti darapọ̀ mọ́ Saulu ní Gilgali. 5Àwọn Filistini kó ara wọn jọ pọ̀ láti bá Israẹli jà, pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) kẹ̀kẹ́, ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ọkùnrin ẹlẹ́ṣin, àwọn ológun sì pọ̀ bí yanrìn etí Òkun. Wọ́n sì gòkè lọ, wọ́n dó ní Mikmasi ní ìhà ilẹ̀ oòrùn Beti-Afeni. 6Nígbà tí àwọn ọkùnrin Israẹli sì rí i pé àwọn wà nínú ìpọ́njú àti pé àwọn ológun wọn wà nínú ìhámọ́, wọ́n fi ara pamọ́ nínú ihò àti nínú igbó láàrín àpáta, nínú ọ̀fìn, àti nínú kànga gbígbẹ. 7Àwọn Heberu mìíràn tilẹ̀ kọjá a Jordani sí ilẹ̀ Gadi àti Gileadi.
Saulu wà ní Gilgali síbẹ̀, gbogbo àwọn ọ̀wọ́ ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì ń wárìrì fún ìbẹ̀rù.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.