1 Samuẹli 13:19
1 Samuel 13:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
A kò sì rí alágbẹ̀dẹ kan ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli, nítorí tí àwọn Filistini wí pé, “Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ àwọn Heberu yóò rọ idà tàbí ọ̀kọ̀!”
1 Samuel 13:19 in English
1 Samuel 13:19 · Berean Standard Bible
And no blacksmith could be found in all the land of Israel, because the Philistines had said, “The Hebrews must not be allowed to make swords or spears.”
Context
17Ẹgbẹ́ àwọn onísùmọ̀mí mẹ́ta jáde lọ ní àgọ́ àwọn Filistini ní ọnà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ẹgbẹ́ kan gba ọ̀nà ti Ofira ní agbègbè ìlú Ṣuali, 18òmíràn gba ọ̀nà Beti-Horoni, ẹ̀kẹta sí ìhà ibodè tí ó kọjú sí àfonífojì Seboimu tí ó kọjú sí ijù. 19A kò sì rí alágbẹ̀dẹ kan ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli, nítorí tí àwọn Filistini wí pé, “Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ àwọn Heberu yóò rọ idà tàbí ọ̀kọ̀!” 20Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Israẹli tọ àwọn Filistini lọ láti pọ́n dòjé wọn, ọ̀kọ̀, àáké àti ọ̀ṣọ́ wọn. 21Iye tí wọ́n fi pọ́n dòjé àti ọ̀kọ̀ jẹ́ ọwọ́ méjì nínú ìdámẹ́ta ṣékélì, àti ìdámẹ́ta ṣékélì fún pípọ́n òòyà-irin tí ilẹ̀, àáké àti irin ọ̀pá olùṣọ́ màlúù.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.