1 Samuẹli 12:9
1 Samuel 12:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ṣùgbọ́n wọ́n gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tà wọ́n sí ọwọ́ àwọn Sisera, olórí ogun Hasori, àti sí ọwọ́ àwọn Filistini àti sí ọwọ́ ọba Moabu, tí ó bá wọn jà.
1 Samuel 12:9 in English
1 Samuel 12:9 · Berean Standard Bible
But they forgot the LORD their God, and He sold them into the hand of Sisera the commander of the army of Hazor,* and into the hands of the Philistines and the king of Moab, who fought against them.
Context
7Nísinsin yìí, ẹ dúró níbi, nítorí èmi ń lọ láti bá a yín sọ̀rọ̀ níwájú Olúwa ní ti gbogbo ìṣe òdodo rẹ̀ tí ó ti ṣe fún un yín àti fún àwọn baba yín. 8“Lẹ́yìn ìgbà tí Jakọbu wọ Ejibiti, wọ́n ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa sì rán Mose àti Aaroni, tí wọ́n mú àwọn baba ńlá yín jáde láti Ejibiti láti mú wọn jókòó níbí yìí. 9“Ṣùgbọ́n wọ́n gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tà wọ́n sí ọwọ́ àwọn Sisera, olórí ogun Hasori, àti sí ọwọ́ àwọn Filistini àti sí ọwọ́ ọba Moabu, tí ó bá wọn jà. 10Wọ́n kégbe pe Olúwa, wọ́n sì wí pé, ‘Àwa ti ṣẹ̀; a ti kọ Olúwa sílẹ̀, a sì ti sin Baali, àti Aṣtoreti. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, àwa yóò sì sìn ọ́.’ 11Nígbà náà ni Olúwa rán Jerubbaali, Bedani, Jefta àti Samuẹli, ó sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá a yín gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń gbé ní àlàáfíà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.