1 Samuẹli 12:14
1 Samuel 12:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ẹ̀yin bá bẹ̀rù Olúwa àti bí ẹ̀yin bá ń sìn ín, tí ẹ sì gbọ́ tirẹ̀, tí ẹ̀yin kò sì ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀, àti tí ẹ̀yin àti ọba tí ó jẹ lórí yín bá ń tẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run yín: ó dára
1 Samuel 12:14 in English
1 Samuel 12:14 · Berean Standard Bible
If you fear the LORD and serve Him and obey His voice, and if you do not rebel against the command of the LORD, and if both you and the king who reigns over you follow the LORD your God, then all will be well.*
Context
12“Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin sì rí i pé Nahaṣi ọba àwọn Ammoni dìde sí i yín, ẹ sọ fún mi pé, ‘Rárá, àwa ń fẹ́ ọba tí yóò jẹ́ lórí wa,’ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa Ọlọ́run yín jẹ́ ọba yín. 13Nísinsin yìí èyí ni ọba tí ẹ̀yin ti yàn, tí ẹ̀yin béèrè fún; wò ó, Olúwa ti fi ọba jẹ lórí yín. 14Bí ẹ̀yin bá bẹ̀rù Olúwa àti bí ẹ̀yin bá ń sìn ín, tí ẹ sì gbọ́ tirẹ̀, tí ẹ̀yin kò sì ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀, àti tí ẹ̀yin àti ọba tí ó jẹ lórí yín bá ń tẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run yín: ó dára 15ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá gbọ́ tí Olúwa, tí ẹ sì ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ yóò wà lára yín sí ibi, bí ó ti wà lára baba yín. 16“Nítorí náà, ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì wo ohun ńlá yìí tí Olúwa fẹ́ ṣe ní ojú u yín!
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.