1 Samuẹli 11:3
1 Samuel 11:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn àgbàgbà Jabesi sì wí fún un pé, “Fún wa ní ọjọ́ méje kí àwa lè rán oníṣẹ́ sí gbogbo Israẹli; àti agbègbè bí ẹni kankan kò bá sì jáde láti gbà wá, àwa yóò fi ara wa fún ọ.”
1 Samuel 11:3 in English
1 Samuel 11:3 · Berean Standard Bible
“Hold off for seven days,” replied the elders of Jabesh, “and let us send messengers throughout Israel. If there is no one to save us, we will surrender to you.”
Context
1Nahaṣi ará Ammoni gòkè lọ, ó sì dó ti Jabesi Gileadi, gbogbo ọkùnrin Jabesi sì wí fún Nahaṣi pé, “Bá wa dá májẹ̀mú, àwa yóò sì máa sìn ọ́.” 2Ṣùgbọ́n Nahaṣi ará Ammoni sì wí fún un pé, “Nípa èyí ni èmi yóò fi bá a yín ṣe ìpinnu, nípa yíyọ gbogbo ojú ọ̀tún yín kúrò, èmi yóò ṣì fi yín ṣe ẹlẹ́yà lójú gbogbo Israẹli.” 3Àwọn àgbàgbà Jabesi sì wí fún un pé, “Fún wa ní ọjọ́ méje kí àwa lè rán oníṣẹ́ sí gbogbo Israẹli; àti agbègbè bí ẹni kankan kò bá sì jáde láti gbà wá, àwa yóò fi ara wa fún ọ.” 4Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà sì wá sí Gibeah tí ó jẹ́ ìlú Saulu, wọ́n sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn, gbogbo wọn gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sọkún. 5Nígbà náà gan an ni Saulu padà wá láti pápá, pẹ̀lú màlúù rẹ̀, ó sì béèrè pé, “Kín ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn? Èéṣe tí wọ́n fi ń sọkún?” Nígbà náà ni wọ́n tún sọ fún wọn ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin Jabesi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.