Native Bible

1 Samuel 10:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí gbogbo àwọn tí ó ti mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀ rí i tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú àwọn wòlíì, wọ́n bi ara wọn, “Kí ni ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí ọmọ Kiṣi yìí. Ṣé Saulu wà lára àwọn wòlíì ni?”

1 Samuel 10:11 in English

1 Samuel 10:11 · Berean Standard Bible

All those who had formerly known Saul and saw him prophesying with the prophets asked one another, “What has happened to the son of Kish? Is Saul also among the prophets?”

Context

9Bí Saulu ti yípadà láti fi Samuẹli sílẹ̀, Ọlọ́run yí ọkàn Saulu padà àti pé gbogbo àmì wọ̀nyí sì wá sí ìmúṣẹ ní ọjọ́ náà. 10Nígbà tí wọ́n dé òkè Gibeah náà, àwọn wòlíì tí ó ń tò ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ pàdé rẹ̀, Ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé e nínú agbára, ó sì darapọ̀ bá wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀. 11Nígbà tí gbogbo àwọn tí ó ti mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀ rí i tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú àwọn wòlíì, wọ́n bi ara wọn, “Kí ni ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí ọmọ Kiṣi yìí. Ṣé Saulu wà lára àwọn wòlíì ni?” 12Ọkùnrin kan tí ó ń gbé níbẹ̀ dáhùn pé, “Ta ni baba wọn?” Ó ti di ohun tí a fi ń pa òwe pé, ǹjẹ́ Saulu náà wà lára àwọn wòlíì bí? 13Lẹ́yìn tí Saulu dákẹ́ sísọ àsọtẹ́lẹ̀, ó lọ sí ibi gíga.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.