1 Samuẹli 1:19
1 Samuel 1:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n sì dìde ni kùtùkùtù òwúrọ̀, wọn wólẹ̀ sìn níwájú Olúwa, wọn padà wa sí ilé wọn ni Rama: Elkana si mọ Hana aya rẹ̀: Olúwa sì rántí rẹ̀.
1 Samuel 1:19 in English
1 Samuel 1:19 · Berean Standard Bible
The next morning Elkanah and Hannah got up early to bow in worship before the LORD, and then returned home to Ramah. And Elkanah had relations with his wife Hannah, and the LORD remembered her.
Context
17Eli dáhùn pé, “Máa lọ ní àlàáfíà, kí Ọlọ́run Israẹli fi ohun tí ìwọ ti béèrè ní ọwọ́ rẹ̀ fún ọ.” 18Ó wí pé, “Kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ rí oore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin náà bá tirẹ̀ lọ, ó sì jẹun, kò sì fa ojú ro mọ́. 19Wọ́n sì dìde ni kùtùkùtù òwúrọ̀, wọn wólẹ̀ sìn níwájú Olúwa, wọn padà wa sí ilé wọn ni Rama: Elkana si mọ Hana aya rẹ̀: Olúwa sì rántí rẹ̀. 20Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ rẹ̀ pé, lẹ́yìn ìgbà tí Hana lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Samuẹli, pé, “Nítorí tí mo béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ Olúwa.” 21Ọkùnrin náà Elkana, àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, gòkè lọ láti rú ẹbọ ọdún sí Olúwa, àti láti sán ẹ̀jẹ́ rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.