Native Bible

1 Peter 5:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ máa wà ni àìrékọjá, ẹ máa ṣọ́ra; nítorí èṣù ọ̀tá yín, bí i kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń rìn káàkiri, ó ń wa ẹni tí yóò pajẹ.

1 Peter 5:8 in English

1 Peter 5:8 · Berean Standard Bible

Be sober-minded and alert. Your adversary the devil prowls around like a roaring lion, seeking someone to devour.

Context

6Nítorí náà, ẹ rẹ ara yin sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára Ọlọ́run, kí òun lè gbe yín ga lákokò. 7Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lé e; nítorí tí òun ń ṣe ìtọ́jú yín. 8Ẹ máa wà ni àìrékọjá, ẹ máa ṣọ́ra; nítorí èṣù ọ̀tá yín, bí i kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń rìn káàkiri, ó ń wa ẹni tí yóò pajẹ. 9Ẹ kọ ojú ìjà sí i pẹ̀lú ìdúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́, bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé ìyà kan náà ni àwọn ará yín tí ń bẹ nínú ayé ń jẹ. 10Ọlọ́run oore-ọ̀fẹ́ gbogbo, tí ó ti pè yín sínú ògo rẹ̀ tí kò nípẹ̀kun nínú Kristi Jesu, nígbà tí ẹ̀yin bá ti jìyà díẹ̀, òun tìkára rẹ̀, yóò sì ṣe yín ní àṣepé, yóò fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, yóò fún yín lágbára, yóò fi ìdí yín kalẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.