Native Bible

1 Peter 3:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá jìyà nítorí òdodo, a ti bùkún yín. “Ẹ má ṣe bẹ̀rù ìhàlẹ̀ wọn, kí ẹ má sì ṣe kọminú.”

1 Peter 3:14 in English

1 Peter 3:14 · Berean Standard Bible

But even if you should suffer for what is right, you are blessed. “Do not fear what they fear; do not be shaken.”*

Context

12Nítorí ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ẹ̀bẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú.” 13Tá nì yóò sì ṣe yín ní ibi, bí ẹ̀yin bá jẹ́ onítara sí ohun rere? 14Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá jìyà nítorí òdodo, a ti bùkún yín. “Ẹ má ṣe bẹ̀rù ìhàlẹ̀ wọn, kí ẹ má sì ṣe kọminú.” 15Ṣùgbọ́n ẹ bọ̀wọ̀ fún Kristi bí Olúwa ní ọkàn yín: kí ẹ sì múra tan nígbà gbogbo láti dá olúkúlùkù lóhùn tí ń béèrè ìrètí tí o ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn tútù àti ìbẹ̀rù. 16Kí ẹ máa ni ẹ̀rí ọkàn rere bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ yín ní ibi, kí ojú lè ti àwọn tí ń kẹ́gàn ìwà rere yín nínú Kristi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.