Native Bible

1 Peter 2:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀yin pẹ̀lú, bí òkúta ààyè, ni a kọ́ ní ilé ẹ̀mí, àlùfáà mímọ́, láti máa rú ẹbọ ẹ̀mí, tí i ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípa Jesu Kristi.

1 Peter 2:5 in English

1 Peter 2:5 · Berean Standard Bible

you also, like living stones, are being built into a spiritual house to be a holy priesthood, offering spiritual sacrifices acceptable to God through Jesus Christ.

Context

3nísinsin yìí tí ẹ̀yin ti tọ́ ọ wò pé rere ni Olúwa. 4Ẹni tí ẹ̀yin ń tọ̀ bọ̀, sí bi òkúta ààyè náà, èyí ti a ti ọwọ́ ènìyàn kọ̀ sílẹ̀ nítòótọ́, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àṣàyàn òkúta iyebíye. 5Ẹ̀yin pẹ̀lú, bí òkúta ààyè, ni a kọ́ ní ilé ẹ̀mí, àlùfáà mímọ́, láti máa rú ẹbọ ẹ̀mí, tí i ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípa Jesu Kristi. 6Nítorí nínú Ìwé Mímọ́, ó wí pe: “Kíyèsi i, mo fi pàtàkì òkúta igun ilé àṣàyàn, iyebíye, lélẹ̀ ni Sioni: ẹni tí ó bá sì gbà á gbọ́ ojú kì yóò tì í.” 7Báyìí fún ẹ̀yin ti ẹ gbà á gbọ́, ó ṣe iyebíye; ṣùgbọ́n fún àwọn tí kò gbà á gbọ́, “Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀, òun ni ó di pàtàkì igun ilé,”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.