1 Peteru 2:12
1 Peter 2:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí ìwà yín láàrín àwọn aláìkọlà dára; pé, bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ yín bí olùṣe búburú, nípa iṣẹ́ rere yín tí wọn ó máa kíyèsi, kí wọ́n lè máa yin Ọlọ́run lógo lọ́jọ́ ti òun ba bẹ̀ wá wò.
1 Peter 2:12 in English
1 Peter 2:12 · Berean Standard Bible
Conduct yourselves with such honor among the Gentiles that, though they slander you as evildoers, they may see your good deeds and glorify God on the day He visits us.
Context
10Ẹ̀yin tí kì í ṣe ènìyàn nígbà kan rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin ti di ènìyàn Ọlọ́run, ẹ̀yin tí kò rí àánú gbà rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ ti rí àánú gbà. 11Olùfẹ́ ọ̀wọ́n, mo bẹ̀ yín, bí àjèjì àti àtìpó, láti fàsẹ́yìn kúrò nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, tí ń ba ọkàn jagun. 12Kí ìwà yín láàrín àwọn aláìkọlà dára; pé, bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ yín bí olùṣe búburú, nípa iṣẹ́ rere yín tí wọn ó máa kíyèsi, kí wọ́n lè máa yin Ọlọ́run lógo lọ́jọ́ ti òun ba bẹ̀ wá wò. 13Ẹ máa tẹríba fún gbogbo ìlànà ènìyàn nítorí ti Olúwa, ìbá à ṣe fún ọba tàbí fún olórí. 14Tàbí fún àwọn baálẹ̀, fún àwọn tí a rán láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti gbẹ̀san lára àwọn tí ń ṣe búburú, àti fún ìyìn àwọn tí ń ṣe rere.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.