1 Peteru 1:7
1 Peter 1:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn wọ̀nyí sì wáyé ki ìdánwò ìgbàgbọ́ yín tí ó ni iye lórí ju wúrà, ti ń ṣègbé lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iná ni a fi ń dán an wò, lè yọrísí ìyìn àti ògo àti ọlá ni ìgbà ìfarahàn Jesu Kristi.
1 Peter 1:7 in English
1 Peter 1:7 · Berean Standard Bible
so that the proven character of your faith—more precious than gold, which perishes even though refined by fire—may result in praise, glory, and honor at the revelation of Jesus Christ.
Context
5ẹyin tí a ń pamọ́ nípa agbára Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ si ìgbàlà, tí a múra láti fihàn ní ìgbà ìkẹyìn. 6Ẹ yọ̀ nínú èyí púpọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pe nísinsin yìí fún ìgbà díẹ̀, níwọ̀n bí ó ti yẹ, a ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdánwò bá yín nínú jẹ́. 7Àwọn wọ̀nyí sì wáyé ki ìdánwò ìgbàgbọ́ yín tí ó ni iye lórí ju wúrà, ti ń ṣègbé lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iná ni a fi ń dán an wò, lè yọrísí ìyìn àti ògo àti ọlá ni ìgbà ìfarahàn Jesu Kristi. 8Ẹni tí ẹ̀yin fẹ́ láìrí, ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò rí i nísinsin yìí ẹ̀yin sì ń yọ ayọ̀ tí a kò lè fi ẹnu sọ, tí ó sì kún fún ògo; 9ẹyin sì ń gba ìlépa ìgbàgbọ́ yín, àní ìgbàlà ọkàn yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.