1 Ọba 9:10
1 Kings 9:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́yìn ogún ọdún, nígbà tí Solomoni kọ́ ilé méjèèjì yìí tan: ilé Olúwa àti ààfin ọba.
1 Kings 9:10 in English
1 Kings 9:10 · Berean Standard Bible
Now at the end of the twenty years during which Solomon built these two houses, the house of the LORD and the royal palace,
Context
8Àti ilé yìí tí ó ga, ẹnu yóò sì ya olúkúlùkù ẹni tí ó kọjá lẹ́bàá rẹ̀, yóò sì pòṣé, wọn ó sì wí pé, ‘Èéṣe tí Olúwa fi ṣe irú nǹkan yìí sí ilẹ̀ yìí àti ilé yìí?’ 9Àwọn ènìyàn yóò sì dáhùn wí pé, ‘Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ Olúwa Ọlọ́run wọn sílẹ̀, tí ó mú àwọn baba wọn jáde láti Ejibiti wá, wọ́n sì ti gbá ọlọ́run mìíràn mú, wọ́n ń bọ wọ́n, wọ́n sì ń sìn wọ́n, ìdí nìyìí tí Olúwa ṣe mú gbogbo ìjàǹbá yìí wá sórí wọn.’ ” 10Lẹ́yìn ogún ọdún, nígbà tí Solomoni kọ́ ilé méjèèjì yìí tan: ilé Olúwa àti ààfin ọba. 11Solomoni ọba sì fi ogún ìlú ní Galili fún Hiramu ọba Tire, nítorí tí Hiramu ti bá a wá igi kedari àti igi firi àti wúrà gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìfẹ́ rẹ̀. 12Ṣùgbọ́n nígbà tí Hiramu sì jáde láti Tire lọ wo ìlú tí Solomoni fi fún un, inú rẹ̀ kò sì dùn sí wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.