1 Ọba 8:30
1 Kings 8:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ àti ti Israẹli, ènìyàn rẹ nígbà tí wọ́n bá gbàdúrà sí ibí yìí. Gbọ́ láti ọ̀run wá láti ibùgbé rẹ, àti nígbà tí o bá gbọ́, dáríjì.
1 Kings 8:30 in English
1 Kings 8:30 · Berean Standard Bible
Hear the plea of Your servant and of Your people Israel when they pray toward this place. May You hear from heaven, Your dwelling place. May You hear and forgive.
Context
28Síbẹ̀ ṣe ìfetísílẹ̀ àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ fún àánú, Olúwa Ọlọ́run mi. Gbọ́ ẹkún àti àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ̀ ń gbà níwájú rẹ lónìí. 29Jẹ́ kí ojú rẹ ṣí sí ilé yìí ní òru àti ní ọ̀sán, ibí yìí tí ìwọ ti wí pé, orúkọ mi yóò wà níbẹ̀, nítorí ìwọ yóò gbọ́ àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ gbà sí ibí yìí. 30Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ àti ti Israẹli, ènìyàn rẹ nígbà tí wọ́n bá gbàdúrà sí ibí yìí. Gbọ́ láti ọ̀run wá láti ibùgbé rẹ, àti nígbà tí o bá gbọ́, dáríjì. 31“Nígbà tí ẹnìkan bá ṣẹ̀ sí ẹnìkejì rẹ̀, tí a sì fi wá lé e láti mú un búra, bí ìbúra náà bá sì dé iwájú pẹpẹ rẹ ní ilé yìí, 32nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run, kí o sì ṣe. Kí o sì ṣèdájọ́ láàrín àwọn ìránṣẹ́ rẹ, dá ènìyàn búburú lẹ́bi, kí o sì mú wá sí orí òun tìkára rẹ̀ ohun tí ó ti ṣe, dá olóòtítọ́ láre, kí a sì fi ẹsẹ̀ àìlẹ́bi rẹ̀ múlẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.