1 Ọba 7:24
1 Kings 7:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ìsàlẹ̀ etí rẹ̀, kókó wá yí i ká, mẹ́wàá nínú ìgbọ̀nwọ́ kan. Ó yí agbádá náà káàkiri, a dá kókó náà ní ọ̀wọ́ méjì, nígbà tí a dá a.
1 Kings 7:24 in English
1 Kings 7:24 · Berean Standard Bible
Below the rim, ornamental buds encircled it, ten per cubit all the way around the Sea, cast in two rows as a part of the Sea.
Context
22Àwọn ìparí lókè sì jẹ́ àwòrán lílì. Bẹ́ẹ̀ ni iṣẹ́ ti àwọn ọ̀wọ́n sì parí. 23Ó sì ṣe agbádá dídá, ó ṣe bíríkítí, ó wọn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti etí kan dé èkejì àti ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gíga rẹ̀. Ó sì gba okùn ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ láti wọ́n yí i ká. 24Ní ìsàlẹ̀ etí rẹ̀, kókó wá yí i ká, mẹ́wàá nínú ìgbọ̀nwọ́ kan. Ó yí agbádá náà káàkiri, a dá kókó náà ní ọ̀wọ́ méjì, nígbà tí a dá a. 25Ó sì dúró lórí màlúù méjìlá, mẹ́ta kọjú sí àríwá, mẹ́ta sì kọjú sí ìwọ̀-oòrùn, mẹ́ta kọjú sí gúúsù, mẹ́ta sì kọjú sí ìlà-oòrùn. Agbada náà sì jókòó lórí wọn, gbogbo apá ẹ̀yìn wọn sì ń bẹ nínú. 26Ó sì nípọn tó ìbú àtẹ́lẹwọ́, etí rẹ̀ sì dàbí etí ago, bí ìtànná lílì. Ó sì gba ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ìwọ̀n bati.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.