Native Bible

1 Kings 7:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lókè ni òkúta iyebíye wà nípa ìwọ̀n òkúta tí a gbẹ́ àti igi kedari.

1 Kings 7:11 in English

1 Kings 7:11 · Berean Standard Bible

Above these were high-grade stones, cut to size, and cedar beams.

Context

9Gbogbo wọ̀nyí láti òde dé apá àgbàlá ńlá, àti láti ìpìlẹ̀ dé ìbòrí òkè ilé, wọ́n sì jẹ́ òkúta iyebíye gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n òkúta gbígbẹ, tí a fi ayùn rẹ́ nínú àti lóde. 10Ìpìlẹ̀ náà jẹ́ òkúta iyebíye, àní òkúta ńlá ńlá, àwọn mìíràn wọn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá, àwọn mìíràn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́jọ. 11Lókè ni òkúta iyebíye wà nípa ìwọ̀n òkúta tí a gbẹ́ àti igi kedari. 12Àgbàlá ńlá náà yíkákiri ògiri pẹ̀lú ọ̀wọ́ mẹ́ta òkúta gbígbẹ́ àti ọ̀wọ́n kan igi ìdábùú ti kedari, bí ti inú lọ́hùn ún àgbàlá ilé Olúwa pẹ̀lú ìloro rẹ̀. 13Solomoni ọba ránṣẹ́ sí Tire, ó sì mú Hiramu wá,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.